Ayinde Barrister bẹ̀rẹ̀ sí ní kọrin láti ìgbà èwe rẹ́ wá gẹ́gẹ́ bíi olórin ajíwéré ní ìgbà ọdún Ramadan; ó tẹ̀ síwájú nípa kí kọrin lóde. Ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi akọ̀wé fún ilé-isé Nigerian breweries àti fún Nigerian Army ní ìgbà ogun abẹ́lé Nàìjíríà. Ó sìn ní ibi ẹgbẹ́ ọmọ ogun kẹwàá tí ìpín kejì ẹgbẹ́ ọmọ ogun Nàìjíríà lábẹ́ ọ̀gágun Adeniran tó sì jagun ní ìlú Awka, Abagana àti onitsha. Ní ìpadà bọ rẹ̀ láti ogun náà, wọn gbé e lọ sí Army signal headquarters, Ní Apapa, wọ́n sì tún padà gbé e lọ sí Army resettlement Center ní Oshodi. Ó padà fi ìṣe ogun jíjà sílẹ̀ lọ gbájúmọ́ ìṣe orin ní kíkọ, tí ó sì ní ẹgbẹ́ orin kíkọ tí ó ní olórin(ọmọ ẹgbẹ́) mẹ́rìndínlógún (34) tí wọ́n pe orúkọ egbẹ́ wọn ní "Supreme Fuji Commanders".
Ní ọdún 1966,Ayinde Barrister gbé àwo orin rẹ̀ àkọ́kọ́ jáde. Ní ìgbà náà, ó sábà máa ń kọrin pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ rẹ̀ ní ibi ayẹyẹ lágbègbè Ebute Mẹta ní Ìpínlẹ̀ Eko fún àwọn oní-ìbárà rẹ̀ tí ó jẹ́ Mùsùlùmí (Muslim). Ó tẹ̀ ṣíwájú nípa gbígbé àwọn oríṣi àwo orin jáde lábẹ́ ilé-isé ìgbórinjáde African songs Ltd kí ó tó bẹ̀rẹ̀ ilé-isé ti ti ẹ̀, "Siky-oluyole Records". Lára àwọn orin tí ilé-isé ìgbórinjáde Lp lábẹ́ African songs gbé jáde ni Bisimilahi (1977) àti Ilé ayé dùn pupo/love in Tokyo (Indian sound)(1976). Ní ọdún 1980 síwájú, Ayinde Barrister àti orin Fuji ti di ìtẹ́wọ́gbà fún gbogbo ẹ̀sìn ní ìlú. Ó tẹ̀ ṣíwájú láti ṣe oríṣi àwo orin tí ó fi mọ́ Ìwà (1982), Nigeria (1983), Fuji Garbage (1988) àti New Fuji Garbage (1993) lábẹ́ ilé-isé ìgbórinjáde ti ti ẹ̀. Ó ní àwo orin tí ó gbájúmọ́ tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ Reality (2004). Ó ní ìjà pẹ̀lú olórin Fuji mìíràn tí à ń pè ní, Kolington Ayinla ní ọdún 1982.
Ayinde Barrister lọ sí ibi ayẹyẹ ní ìlú London ní ọdún 1990 àti ní ọdún 1993 ní èyí tí ó kọ orin rẹ̀ kan tí à ń pè ní Fuji Garbage.
Orin Fuji rẹ jẹ ọ̀kan lára àwọn oríṣi orin ìbílẹ̀ ti Apala, Sakara, Awurebe, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Pẹ̀lú orin Fuji, Barrister mú orin ìbílẹ̀ Yorùbá ní ọ̀kúkúndùn ní ìgbà tí ó sì tún ṣe ìfihàn èrè Ìwà réré, ìbọ̀wọ̀ fún àgbà àti ìjàkadì tí ó lòdì sí ayé ọmọ ẹ̀dá. Ó máa ń lo orin rẹ̀ fi dá sí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀/rògbòdìyàn tí ó bá ń ṣẹlẹ̀ ní ìlú,pàápàá òṣèlú. Ó ní ẹ̀bùn kí ó máa fi orin rẹ̀ sọ nnkan mériìírí.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Sikiru Ayinde Barrister gba oríṣi àmì-ẹ̀yẹ ní ìgbà ayé rẹ̀, ẹ̀yẹ tí ó lọ́ọ̀rìn tí ó gbà ni jíjẹ́ ọkàn lára àwọn ọmọ ẹgbẹ́ MFR( Member of the Order of the Federal Republic) láti owó Ààrẹ ìgbà náà ní orílè-èdè Nàìjíríà ní ọdún 2006,Ààrẹ Olusegun Obasanjo. Àmì ẹ̀yẹ tí ó gbà yí wáyé látàrí àwo orin tí ó fi lé de (kọ) ní ọdún 1995, àwo orin ọ̀hún ṣàlàyé ní kíkún lórí ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ń dojú kọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà gẹ́gẹ́ bí ìlú tí orin ọ̀hún sì tún ṣàlàyé ọ̀nà àbáyọ tí ó ń dojú kọ Nàìjíríà ní ìgbà náà. Ní ọdún 1983, wọ́n fún un ní ẹ̀yẹ PHD orin ní City university tí ìlú Los Angeles.
Èyí ni àwọn orin rẹ̀ :
Ejeka Gbo T'Olorun
- Vol.1: Waya Rabi
- Vol.2: Alayinde Ma De O
- Vol.3: Mecca Special
- Vol.4: Itan Anobi Rasao
- Vol.5: E Sa Ma Mi Lengbe
- Vol.6: Ori Mi Ewo Ninse / Majority Boy(1975)
- Vol.7: Ile Aiye Dun Pupo / Love in Tokyo (India Sound)(1975)
- Vol.8: Fuji Exponent(1976)
- Vol.9
- Vol. 10(African Songs, 1977)
- Bisimilai(African Songs, 1977)
- Omo Nigeria(African Songs, 1977)
- Olojo Eni Mojuba(Siky Oluyole, 1978)
- Our Late Artistes(Siky Oluyole, 1978)
- London Special(Siky Oluyole, 1979)
- Fuji Reggae Series 2(Siky Oluyole, 1979)
- Eyo Nbo Anobi(Siky Oluyole, 1979)
- Awa O Ja(Siky Oluyole, 1979)
- Fuji Disco(Siky Oluyole, 1980)
- Oke Agba(Siky Oluyole, 1980)
- Aiye(Siky Oluyole, 1980)
- Family Planning(Siky Oluyole, 1981)
- Suru Baba Iwa(Siky Oluyole, 1981)
- Ore Lope(Siky Oluyole, 1981)
- E Sinmi Rascality(Siky Oluyole, 1982)
- Iwa(Siky Oluyole, 1982)
- Ise Logun Ise (No More War)(Siky Oluyole, 1982)
- Eku Odun(Siky Oluyole, 1982)
- Ijo Olomo(Siky Oluyole, 1983)
- Nigeria(Siky Oluyole, 1983)
- Love(Siky Oluyole, 1983)
- Barry Special(Siky Oluyole, 1983)
- Military(Siky Oluyole, 1984)
- Appreciation(Siky Oluyole, 1984)
- Fuji Vibration 84/85(Siky Oluyole, 1984)
- Destiny(Siky Oluyole, 1985)
- Superiority(Siky Oluyole, 1985)
- Fertiliser(Siky Oluyole, 1985)
- Okiki(Siky Oluyole, 1986)
- Inferno(Siky Oluyole, 1996)
- America Special(Siky Oluyole, 1986)
- Ile Aye Ogun(Siky Oluyole, 1987)
- Maturity(Siky Oluyole, 1987)
- Barry Wonder(Siky Oluyole, 1987)
- Wonders at 40(Siky Oluyole, 1987)
- Fuji Garbage(Siky Oluyole, 1988)
- Fuji Garbage Series II(Siky Oluyole, 1988)
- Current Affairs(Siky Oluyole, 1989)
- Fuji Garbage Series III(Siky Oluyole, 1989)
- Music Extravaganza(Siky Oluyole, 1990)
- Fuji Waves(Siky Oluyole, 1991)
- Fantasia Fuji(Siky Oluyole, 1991)
- Fuji Explosion(Siky Oluyole, 1992)
- Dimensional Fuji(Siky Oluyole, 1993)
- New Fuji Garbage(Siky Oluyole, 1993)
- The Truth(Siky Oluyole, 1994)
- Precaution(Siky Oluyole, 1995)
- Olympics Atlanta '96cassette (Siky Oluyole, 1996)
- Olympics '96London Version cassette (Zmirage Productions, 1997)
- with Queen Salawa Abeni Evening Of Soundcassette (Zmirage Productions, 1997)
- Barry On Stagecassette (Siky Oluyole, 1997)
- Democracy(Siky Oluyole, 1999)
- Mr. Fuji(Barry Black, 1998)
- "Millennium Stanza" (Fuji Chambers, 2000)
- "Controversy" (2005)
- ' Reality and Questionnaire ' ( 2008).
- Superiority
- Fuji Booster
- Fuji Missile
- Wisdom and correction
- Image and Gratitude