Ní ọdún 1951, ó fẹ́ ìyàwó rẹ̀ Àgbékẹ́ Akínlàdé. Ìlaròó ni ó ṣì wà nígbà ó kọ́ ara rẹ̀ ṣe ìdánwò G.C.E. tí University of London gbékalẹ̀. Latí ara àṣeyọrí rẹ̀ nínú àwọn ìdánwò rẹ̀, wọ́n pè é láti wá kẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ òfin ní ìlú London ní ọdún 1952. Akínlàdé kò le è lọ sí ìlu London láti lọ kẹ́kọ̀ọ́ nítorí àìlówó. Látàrí àìlèlọ sí London, Akínlàdé dá ìwé-ìròyìn ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ “Ẹ̀gbádò Progressive Newspaper” sílẹ̀. Láàárín ọdún 1966 sí 1969, ó kẹ́kọ̀ọ́ ní Obafemi Awolowo University.
Ọdún 1971 ni Akínlàdé bẹ̀rẹ̀ sí ní tẹ àwọn ìtàn-àròsọ ọlọ́rọ̀ geere ọ̀tẹlẹ̀múyé rẹ̀ jade. Ìwé ìtàn-àròsọ ọlọ́rọ̀ geere rẹ̀ tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Ogun Ìdàhọ̀mì àti àwọn ará ìlú Ọbọgíran gba ipò kẹ́ta nínú ìdíje “Nigerian Festival of the Arts.” Kọ́lá Akínlàdé ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìwé mìíràn tí ó kọ. Bí i Ìjọba Káúnsùlù (1959), Ìtàn Sọlómónì Ọba Ṣúlámítè Arẹwà Obìnrin (1959) Òwe Pẹ̀lú Ìtumọ̀ (1987), Ajá tó ń lépa Ẹkùn, Owó Ẹ̀jẹ̀ (1986), Ṣàǹgbá fọ́ (1986), Àṣírí Amòòkùnjalè Tú (2000), Ọmọ́gbèjà (2004). Ọmọ́gbèjà nìkan ni ìwé eré-onítàn tí Kọ́lá Akínlàdé kọ́. Ìwé Òwe Pẹ̀lú Ìtumọ̀ tí Akínlàdé kọ jẹ́ àkójọpọ̀ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta òwe Yorùbá.
Akínlàdé jẹ́ ọ̀kan gbòógì lára àwọn òǹkọ̀wé ìtàn ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ Yorùbá.